Home News Sé Sèyí Mákindé Ló Lé Ladoja Kúrò Ni PDP Ni?

Sé Sèyí Mákindé Ló Lé Ladoja Kúrò Ni PDP Ni?

985
0Gomina ipinlẹ Ọyọ nigbakan, to tun figbakan ri jẹ aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu Accord, Sẹnetọ Raṣhidi Ladọja ti kuro lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, lọ si ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC.

Ẹsun ti o fi kan ẹgbẹ oṣelu PDP ni pe ẹgbẹ oṣelu naa dalẹ adehun to wa laarin oun ti wọn paapaa lori igbimọ alakoso ẹgbẹ oṣelu naa ti wọn gba gẹgẹ bii eyi gan an to jẹ ootọ ni ipinlẹ Ọyọ.

Raṣhidi Ladọja ṣalaye ọrọ yii lasiko to fi n fikunluku pẹlu awọn ololufẹ rẹ kaakiri ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ Ọyọ ni ile rẹ to wa lagbegbe Bodija nilu Ibadan.Ladọja ni gbogbo awọn to lorukọ ninu igbimọ adari ẹgbẹẹ oṣelu PDP titi kan alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa loun ba sọrọ ti wọn si fi da ohun loju pe igbimọ iṣakoso ẹgbẹ oṣelu naa eleyi ti Lyel Imoke fi lọlẹ ni wọn yoo gba wọle gẹgẹ bii adari ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ, ki wọn to tun gbẹyin lọ tẹwọ gba igbimọ ti Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde gbe kalẹ.

O ni ẹgbẹ oṣelu ADC ti oun wa bayii ti gbe akanṣe iṣẹ nla le oun lọwọ lati rii daju pe awọn gomina kan darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa kaakiri tibu toro orilẹede Naijiria, eleyi to ni yoo bẹrẹ pẹlu agbekalẹ idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu naa lati wọọdu titi de ẹka ti ipinlẹ laipẹ.

Leave a Reply