Home News Samuel Ladoke Akintọla: Awọn Ohun To Yẹ Ko Mọ Nipa E

Samuel Ladoke Akintọla: Awọn Ohun To Yẹ Ko Mọ Nipa E

1872
0

Samuel Ladoke Akintọla jẹ ojulowo ọmọ Yoruba to ko ipa manigbagbe ni saa isejọba alagbada akọkọ ni orilẹede Naijiria.

Agba ọjẹ oloselu ni Akintọla, to si tun jẹ agbẹjọro to moye, bakan naa lo tun jẹ ẹni ti yoo sọrọ, ti yoo dabi ki a pọn ni ete la, tori ọrọ da saka lẹnu rẹ, boya ni ede Yoruba ni, abi Gẹẹsi.

Google search engine

Bi o tilẹ jẹ pe lọdun 1966, eyiun ọdun mejilelaadọta (52) sẹyin, ni wọn gbẹmi Oloye Akintọla lojiji, ti ọpọ̀ ọdọ atawọn agbagba kan ko si baa laye, sibẹ o yẹ ka lee mọ iru isẹ́ ribiribi ti akikanju ọmọ Oodua yii se.

Ọjọ Kẹfa osu Keje ọdun 1910, eyiun ọdun mejidinlaadọfa (108) sẹyin, ni Akinbọla ati Akankẹ bi Samuel Ladoke nilu Ogbomọsọ, to wa nipinlẹ Ọyọ bayii

Ileẹkọ alakọbẹrẹ baptist day lolọ lọdun 1922, to si wọle sile ẹkọ girama lọdun 1925

O sisẹ bii olukọ fun igba diẹ laarin ọdun 1930 si 1942, ko to lọ sisẹ nileesẹ reluwe nibi to ti salabapade H.O Davies

Oun ni Olootu agba fun iwe iroyin Daily Service Newspaper lọdun 1943, to si tun wa lara awọn to da iwe iroyin Iroyin Yoruba silẹ

Samuel Ladoke sisẹ bii Agbẹjọro pẹlu Chris Ogunbanjọ, Bọde Thomas ati Michael Ọdẹsanya

Oun ati awọn eeyan kan, to fi mọ Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ni wọn dijọ da ẹgbẹ oselu Action Group (AG), eyiun ẹgbẹ ọlọpẹ silẹ

Akintọla ati Awolọwọ tako ara wọn lori igbesẹ didapọ mọ ijọba alajumọse ti NPC to n dari orilẹede yii, ti Akintọla si gba pe o yẹ ki Yoruba kopa ninu ijọba naa

Aawọ to wa laarin Awolọwọ ati Akintọla lo mu ki laasigbo bẹ silẹ nile igbimọ asofin lẹkun iwọ oorun Naijiria, nigba ti wọn dibo a ko ni igbẹkẹle ninu rẹ mọ fun Akintọla lọdun 1962

Laasigbo yii lo mu ki onigbo dagbo si meji nile asofin naa, eyi to tan yika gbogbo ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria

Olootu ijọba nigba naa, Ọlọla Abubakar Tafawa Balewa kede pe ẹkun iwọ oorun Naijiria ko fararọ, to si yan Oloye M.A Majẹkodunmi lati rọpo awọn adari ibẹ

Lọdun 1963 ni wọn da Akintọla pada gẹgẹ bii olootu ijọba fẹkun iwọ oorun guusu Naijiria

Akintọla bori ibo pada bii Olootu ijọba ẹkun iwọ oorun Naijiria lọdun 1965 gẹgẹ bii asaaju ẹgbẹ oselu NNDP, to ni ajọsepọ pẹlu NPC to n sejọba loke

Akintọla jẹ eeyan to ni ẹbun agbekalẹ ọrọ sisọ, to jẹ ẹni to kọ ile ẹkọ fasiti Ile Ifẹ, taa mọ si fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ pari lọdun 1962 gẹgẹ Olootu ijọba ẹkun iwọ oorun Naijiria

O tun lọwọ ninu kikọ Ile Itura Premier atawọn ibudo miran, ti wọn si fi Ile ẹkọ fasiti Ladoke Akintọla to wa nilu Ogbomọsọ sọri rẹ

Oloye Faderera Akintọla ni aya Samuel Ladoke, ti Ọlọrun si fi ọmọ marun ta wọn lọrẹ

Samuel Ladoke Akintọla fi aye silẹ nigba ti awọn ologun to fẹ ditẹ gbajọba gbẹmi rẹ ninu ete iditẹ gbajọba akọkọ to waye ni Naijiria lọjọ Kẹẹdogun, osu Kinni ọdun 1966.

Previous articleOyo 2019: Olatubosun Takes Outreach To Aba Panu, Olose, Ire Akari As Hausa Community Adopts Him
Next articleI Will Appoint 3 Education Commissioners — Ayorinde, Oyo SDP Guber Candidate

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here