Gbajugbaja olorin ni, Yinka Ayefẹlẹ ni kọmisana fun eto iroyin ati aṣa nipinlẹ Ọyọ, Toye Arulogun lo wa nidi bi ijọba ṣe fẹ ẹ wo ileeṣẹ igbohun s’afẹfẹ oun, Fresh FM, to wa nilu Ibadan.
Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, Ayefẹlẹ ni oun gba awọn iwe to yẹ ki oun to kọ ile naa. Ati pe ara ijọba ipinlẹ Ọyọ kọ otitọ ọrọ ni wọn ṣe fẹ gbe igbesẹ naa.
O fi ẹsun kan kọmisana naa pe o sọ̀ fun ileeṣẹ redio naa lati da awọn eto kan ‘to n tọka si awọn nkan ti ko dara ninu eto iṣakoso ijọba Gomina Abiola Ajimọbi.
Ẹkunrẹrẹ ọ̀rọ̀ rẹ n bẹ ninu fọnran yii:
Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ ni ijọba kọ lẹta si ileeṣẹ redio Fresh FM pe ko ‘gbe ile naa kuro nibi to wa laarin ọjọ mẹta, bi bẹ ẹ kọ, wọn yoo wo ni.
Ọjọ mẹta naa ti tẹnubodo lọjọ kẹẹdogun.
Sugbọn nigba ti a kan si kọmisana fun eto iroyin ati aṣa nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Toye Arulogun, ti Yinka Ayefẹlẹ fi ẹsun kan pe oun lo wa nidi iṣẹlẹ naa, Arulogun ni ‘ti wọn ba sọ pe oun ni, oun naa ni.’
Ati pe ki i se nkan ti Yinka Ayefẹlẹ sọ pe oun fẹ fi ile naa ṣe nigba to fẹ ẹ gba iwe aṣẹ lo fi ṣe. O ni ko si adehun redio ninu adehun to ba ijọba ṣe.
Ẹwẹ, Kọmisọna fun ọrọ ayika nipinlẹ Ọyọ, Oloye Isaac Ishọla ni ko ni nkankan ṣe pẹlu Yinka Ayefẹlẹ, bi ko ṣe ofin ijọba to sọpe ẹni to ba fẹ ẹ k’ọle gbọdọ fi alafo amita marunlelogoji silẹ si oju popo. Ahesọ nipe tori wọn n sọrọ sijọba ni. Ibi ti wọn kọ ile naa si ko ba ofin mu.
O ni ‘bi ẹẹmẹta nijọba ti kọ lẹta si i, sugbọn ti wọn ko dahun. Ati pe ile naa n fa ijamba.
Eniyan to ti padanu ẹmi wọn lati bi oṣu mẹsan nitori ibi ti ile naa wa , koda osisẹ wọn kan naa jana mọ mọto lẹnu.’