Gomina ipinlẹ Abiọla Ajimọbi ti sọ wi pe ohun yoo wa nnkan ṣe si ọrọ ileeṣẹ gbajugbaja onkọrin Yinka Ayefẹlẹ eleyi to ti di orisun awuyewuye bayii lẹyin ti ijọba wo ile naa ni owurọ ọjọ aiku.
Ninu ọrọ kan to ba awon oniroyin sọ lẹyin to kirun ọdun ileya tan ni yidi ilu Ibadan ni gomina Ajimọbi ti sọ ọrọ yii.
O ni ko si ẹni to tayọ ofin bi o ti wu ki ipo ti ẹni bẹẹ ba wa ṣe lee ri.
Gomina Ajimọbi ni ni iwoye ti oun, ibi ileeṣẹ Ayefẹlẹ wa ko ba ofin mu ati pe awawi ni ohun ti awọn kan n sọ kiri pe akanda ẹda ni o si n gba ọpọlọpọ eeyan siṣẹ.
Gomina ipinlẹ Ọyọ fi ọrọ rẹ we adigunjale to n ṣiṣẹ koto ni.
“Ṣe awọn adigunjale naa ko gba eeyan siṣẹ ni abi ka sọ pe tori pe wọn gba awọn eeyan si ẹnu iṣẹ ka fi wọn silẹ.”