- Ọpọlọpọ kò mọ pe ìyá mi kàwé de ilẹ̀ òkèèrè (Switzerland) nígbà ayé rẹ̀
Doyin Adeoye Ṣonubi, Ọkan lara awọn ọmọ Alhaja Motunrayọ Adeoye to jẹ gbajugbaja òṣèré to jalaisi lọsẹ to kọja, ba BBC Yorùbá sọrọ nipa irú ẹni ti iya rẹ jẹ.
O ni pe, o ya òun lẹnu iru ìfẹ́ ti iya oun ni si baba oun, ti Tunrayọ fi ṣalaisi ni ọjọ Ẹti to pe ọsẹ karun un geerege ti awọn sin ọkọ rẹ, Alagba Johnson Tewogbade Adeoye.
Bi o ṣe fẹran lati maa gba awọn obinrin niyanju naa ni o fẹran lati maa wọ aṣọ ibilẹ.
Doyin ni obinrin ni gbogbo ọmọ ti Ẹlẹdaa fi jíǹkì Motunrayọ Adeoye, bẹẹ, onikaluku ti làlùyó lẹnu iṣẹ to yàn laayo.
O ni ọ̀rọ̀ ìdílé lo jẹ ìyá oun lógún ju nigba ayé rẹ pe, ki obi ṣe ẹ̀tọ́ lori awọn ọmọ wọn, ki ọmọ naa gbọran si obi lẹnu.
Ọmọ oloogbe naa ṣapejuwe Tunrayọ Adeoye pe: Akinkanju eeyan to muṣẹ ẹ lọkunkundun ni iya mi, koda lẹnu iṣẹ ẹkọ nipa ẹrọ to n lo ina to kọ nile iwe paapaa.
Igbagbọ Yorùbá ni pe ilẹ̀ ń jẹ èèyàn, ko si ẹni ti kò ni ku lọjọ kan ṣugbọn ki iku ṣa ká iṣẹ rere mọ onikaluku lọwọ lo dara