Home News Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ògùn, Ọ̀sun, Ati Èkìtì Kéde Isinmi Lọ́jọ́ Kejìla, Oṣù...

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ògùn, Ọ̀sun, Ati Èkìtì Kéde Isinmi Lọ́jọ́ Kejìla, Oṣù Kẹfa

2151
0

Àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní apá Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ògùn, Ọ̀sun, Èkìtì àti Ọ̀yọ́ kéde ọjọ́ kejìlá, oṣù Kẹfà gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́.

 

Google search engine

 

Níbi ìpàdé tí àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà se ni ọ̀rọ̀ yìí ti jáde.

 

Ní ti ìpínlẹ̀ Ògùn, ó jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé fún ìjọba ìpínlẹ̀ nàá, Taiwo Adeoluwa fọwọ́ sí.

 

 

Nínú àtẹ̀jáde nàá tó tẹ ìwé ìròyìn Punch lọ́wọ́, wọ́n ni ọjọ́ nàá yó le fún àwọn aráàlú ní ànfàání láti ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ ìṣèjọba àwaarawa.

 

Ọjọ́ nàá ẹ̀wẹ̀, ni wọ́n yòó tún fi ṣe àjọyọ̀ oyè GCFR tí Ààrẹ Muhammadu Buhari fi dá olóògbé MKO Abiọ̀la lọ́lá láìpẹ́ yìí.

 

Nínú ìròyìn mi, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ nàá ti kéde ọjọ́ nàá ní ọjọ́ ìsìnmi.

 

 

Ṣáàjú ni ìjọba àpapọ̀ tí fi ìkéde kan síta pé kò ní sí ìsìnmi fún àyájọ́ ọjọ́ ìṣèjọba àwaarawa.

Previous articlePeller’s Daughter Says “Dad’s Fame Not Putting Me Under Pressure To Excel”
Next articleỌrọ Ifẹ́: Tunrayọ Adeoye Kú Lọ́sẹ̀ Karun Ti A Sin Okọ Rẹ̀

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here