Home News Sé Ìwo Mo Odò Adágún Adó Àwáyè Tí Kò Ní Òpin Ní...

Sé Ìwo Mo Odò Adágún Adó Àwáyè Tí Kò Ní Òpin Ní Ìsàlè?

1245
0Colorado ni Amẹrika àti Adò Awaye ní Naijiria nikeji àdágún órí àpáta ní gbogbo àgbáyé!

Oriṣii ibudo Kayeefi ló wa lagbaye ni eyi ti Naijiria náà ni awọn ibudo kọọkan to fi agbára Olodumare hàn.

Odò Ado Awaye ni adágún odó ti iwadii fihan pé kò kún rí ní kò sí bi òjò ṣe rọ̀ tó; bẹẹ kò lọlẹ sii ri bó ti wu ki ọ̀gbẹlẹ̀ mu tó lasiko ẹ̀rùn.


Ogbeni Ayo Adams to jẹ alakoso irinajo afẹ́ nibẹ ṣalaye fun BBC Yoruba ni kikun lori odo adagun naa.

O ni awọn kan ti wọn ko sinu odo naa ko pada jade bẹẹ nigba ti wọn sọ okuta sinu odo adagun ọhun, ìlú jinjin si Oyo ni wọn ti lọ ri awọn nkan naa.

Odo adagun meji lo jẹ iru eyi to wa ni gbogbo agbaye.

Okan ni Colorado ni orilẹ-ede Amerika ati ikeji ni odo Adagun Ado Awaye nipinlẹ Oyo lorilẹ-ede Naijiria.

Bẹẹ, nání. nànì, nání, bi ọmọ ọdẹ ṣe n nání apó, ti ọmọ aṣẹgita n naaani epo igi naa lo ṣe yẹ ki awọn ijọba Naijiria naani odo adagun Ado Awaye yii.

Gbogbo awọn ti BBC fọrọwalẹnuwo lori odo adagun Ado Awaye yii ni wọn ke si ijọba lati wa ṣe ohun to yẹ fun ipese ohun amayedẹrun bii akasọ lati gun oke ti omi adagun yii wa ati awọn nkan mii ti yoo sọ ibẹ di ibudo irin ajo afẹ ti gbogbo agbaye a wá maa wò.

Leave a Reply