Ìgbẹ́ ọ̀ọ̀nì yì ti di oògùn ara lílé fáwọn èèyàn kan.
Oloye Raufu Yesufu to jẹ mọ́gàjí ilé Delesolu ti wọn ti n sin ọọni yii ni Ibadan ṣalaye fun BBC Yorùbá pé àwọn baba nla wọn lo bẹrẹ sinsin ọọni naa bi èran ọ̀sìn ninu ilé ni 1940.
Ọọni naa ti wa di eyi ti awọn babalawo ati oniṣegun n mu adìyẹ to tobi wa fun wa fi tọrọ nkan ati lati wa dupẹ fún.
Loju àwọn ọmọ inu ile Delesolu, ‘Àṣà ni kìí ṣe ẹ̀sìn rara’ tori wọn gba pe kò si awo kan láwo ẹ̀wà lori ọọni naa.
Ilé Delesolu ti ọọni yii n gbe sẹ̀ wá lati Ijẹru de agbegbe Oje nilu Ibadan ni ipinlẹ Oyo ni guusu Naijiria.