Home Crime Ìjà Olọ́pàá Ati Alápatà Ni Bodija Gbẹ̀mí Sulia Aláìṣẹ̀ Ni UCH

Ìjà Olọ́pàá Ati Alápatà Ni Bodija Gbẹ̀mí Sulia Aláìṣẹ̀ Ni UCH

2379
0

“Ṣọ́ọ̀bù nìròyìn ti kàn mí pé ìbọn ti ba ìyàwó mi”

Wahala ǹla bẹ́ silẹ̀ laarin àwọn agbofinro ati àwọn alápatà l’ọja Bodija nilu Ibadan.

Google search engine

Àwọn alápatà dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá lọ́jà Bódìjà.

Ọpọlọpọ ọjà lo bajẹ ti ẹmi sọnu ninu ìjà naa.

Yekeen Idowu Ahmad to jẹ ọkọ Sulia Tirimisiyu ba BBC Yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ naa to ṣẹṣẹ mu ẹmi iyawo rẹ lọ nile iwosan UCH bayii latari ibọn agbofinro to ba Sulia lọrun.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ní pàtó

Ahmad ṣapejuwe biyawo rẹ ṣe dagbere ṣọọbu to ti n ranṣọ laarọ ti oun ko mọ pe o n lọ rin arinfẹsẹsi ni.

O ni àwọn ko le tete gbe Sulia lọ sile iwosan nitori awon ọlọpaa ṣi n yìnbọn kikankikan.

Ibrahim Abdusalam to jẹ ẹgbọn Sulia naa ba BBC Yoruba sọrọ pé aburo oun ko tii de ṣọọbu rẹ̀ tíbọn aṣeṣi yin awọn ọlọpaa fi baa.

O ni gbogbo eniyan n gbiyanju lati sá àsálà fun ẹmi wọn ni.

Dokita Adewale Badru to jẹ ọga kan ni ẹka iṣẹlẹ pajawiri nile ìwòsàn UCH ti fasiti Ibadan ba BBC sọrọ lori igbiyanju ti wọn ṣe fun Sulia lori ibi ti ibọn ti baa to ti pa ọpa ẹyin rẹ lara.

Bayii, ohun to bani lọkan jẹ ni pe, Sulia Tirimisiyu ti dero ọrun lataari ìbón awọn agbofinro ni Bodija

Previous articleCourt Restrains Olubadan From Installing Another Mogaji in Jagun Elesin Merindinlogun Compound
Next articleYunus Akintunde Explains How APC ‘Died’ In Oyo, Says Discussions Ongoing With Likeminds

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here