Home Crime Seyi Makinde: Mo Ti Gba ₦1.2bn Padà Lọ́wọ́ Òṣìṣẹ́ Oba Kan, Ti...

Seyi Makinde: Mo Ti Gba ₦1.2bn Padà Lọ́wọ́ Òṣìṣẹ́ Oba Kan, Ti Mo Sì Ti Fi Pamọ́

771
0
Gbogbo ẹni to ba mọ nkan fi pamọ, ko maa ranti ẹni to mọ ọ wa nitori asegbe kankan ko si, asepamọ lo wa.
Idi ree ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde fi n leri leka, to si n tọ ilẹ la pe gbogbo owo ipinlẹ Ọyọ ti awọn alajẹba ba ji ko ni oun yoo gba pada lọwọ wọn, lai ku kọbọ.
Makinde seleri yii lasiko to n gbalejo awọn ọga agba ile ifowopamọ kan lọọfisi rẹ, to si fikun pe gbogbo owo ti oun ba ri gba pada naa ni oun yoo fi pamọ sinu apo asuwọn owo pataki kan nile ifowopamọ.
Bakan naa lo salaye pe ko ni si awo kankan ninu awo ẹwa nipa apo asuwọn owo pataki naa nitori pe oun yoo jẹ ki awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ni anfaani lati mọ nipa bi apo asuwọn owo naa se n lọ si, ko maa ba tun fun ẹnikẹni lanfaani lati ko owo naa jẹ pada.
“O yẹ ki awọn araalu mọ bi ijọba se n na owo wọn. Gbogbo owo ti ajọ EFCC ba gba pada lọwọ alajẹbanu kọọkan ni a gba pada, ta si ko pamọ sinu apo asunwọn naa, eyi ti a maa dari ni ọna ti ko ni sokunkun si awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.”
Makinde fikun pe ni kete ti oun de si ọọfisi gomina, ni oun kofiri owo to to biliọnu kan ati miliọnu lọna igba naira ninu apo asuwọn owo osisẹ ọba kan, ti ijọba si ti gbẹsẹle owo naa.
Gomina ipinlẹ Ọyọ ni oun ti tọ ajọ EFCC lọ lati ba oun gba awọn owo yii pada, lọna ati se atilẹyin fun eto ẹkọ to dẹnu kọlẹ nipinlẹ Ọyọ.

Source: BBC

Leave a Reply