Home News Oyo 2019: Ẹgbẹ́ Olóúnjẹ Ìbàdàn Se Àtìlẹyìn Fún Tegbe, Wọ́n Jẹ́rìí Sí...

Oyo 2019: Ẹgbẹ́ Olóúnjẹ Ìbàdàn Se Àtìlẹyìn Fún Tegbe, Wọ́n Jẹ́rìí Sí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Rẹ̀

1694
0

Ṣáájú ètò ìdìbò kòmẹṣẹ̀-ẹ́-yọ ti àwọn gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress {APC}, Ọ̀gá fún gbogbo àwọn olóúnjẹ ìlú Ìbàdàn lábẹ́ àṣẹ gbogbo ẹgbẹ́ olóúnjẹ ìlú Ìbàdàn, ti ṣe òṣùwọ̀n gbọn-in gbọn-in la wà lẹ́yìn Engr. Joseph Olasunkanmi Tegbe, ẹni tí ó ń díje fún ipò gómìnà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress {APC} ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Olùdarí ẹgbẹ́ Alhaja Busari Bada àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mìíràn káàkiri ìlú Ìbàdàn, níbi tí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ènìyàn ti ń yan olùdíje Tegbe gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n fẹ́ fún ipò gómìnà, tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìsèjọba rẹ̀ yóò rọ t’ẹrú t’ọmọ Ìpínlẹ̀ yìí lọ́rùn. Nítorí pé, Tegbe ló le ṣe é.

Google search engine

Gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ tún ṣe àfikún pé, Tegbe ni ẹni tí ó ní àmúyẹ láti mú àṣeyọrí bá ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ yìí, wọ́n wá rọ gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú ‘APC’ nílé àti lóko Ìpínlẹ̀ yìí, láti ṣe ìrànlọ́wọ́ àti àtìlẹyìn fún ẹni tí ó tó mú Ìtẹ̀síwájú bá iṣẹ́ rere tí Gómìnà Abiọla Ajimọbi ti ṣe.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣe àpèjúwe olùdíje Tegbe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́pọlọ ènìyàn, Aláṣeyọrí lórí gbogbo àdáwọ́-lé rẹ̀, tí ó sì dáni lójú pé yóò lo gbogbo àwọn ìwà rere rẹ̀ wọ̀nyí láti gbé Ìpínlẹ̀ yìí dé èbúté ògo àti láti ṣe àwọn àṣeyọrí aláìlóǹkà nípò gómìnà.

Ó dání lójú pé, olùdíje Tegbe, yóò ro ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ yìí lágbára àti gígùn lé ètò ààbò tó gbó-pọn, léyìí tí ìjọba òde yìí gùn-lè, tí yóò sì le è ló ọgbọ́n, ìmọ̀, ìrírí àti ìbátan ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé láti mú ìlérí rẹ̀ wá sí ìmúṣẹ, kí ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lè rú gọ́gọ́ sí i. Bí a bá le fún un láàyé.

Àwọn Ẹgbẹ́ yìí rọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress {APC} ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti lo olùdíje Tegbe, ẹni tí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé ó tọ́/yẹ fún ipò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, léyìí tí gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ kò sì ní í kábàámọ̀  ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní sí Tegbe pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀, tí kò sì ní í sọ ìrètí wa nù.

Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n níbẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ yìí jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti gbé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress {APC} ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dé èbúté ògo, bí ẹgbẹ́ bá jẹ́ kí ẹni tí ó mọ̀’nà gẹ́gẹ́ bí Tegbe tọ̀ ọ́, òun náà ló tọ́ sí.

Wọ́n ṣàpèjúwe òṣèlú gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àjùmọ̀se, wọ́n sì sọ pé, Tegbe ṣe tán láti sin gbogbo àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pẹ̀lú ìfẹ́, ìfọmọnìyàn-se, ìrẹ̀lẹ̀, ìgbéga, ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti láti mú gbogbo àwọn ìwà wọ̀nyí bá gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Àwọn Ẹgbẹ́ olóúnjẹ yìí kò sàì fèsì lórí àhesọ àwọn ènìyàn pé, Tegbe jẹ ọmọ ọkọ ìlú Ìbàdàn, ẹni tí ó ti ń ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, wọ́n rọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn lè máa ṣe ròyí ròyí tàbí láti fi tó àwọn ènìyàn létí láti kọ etí ọ̀gbọn-ìn sí àhesọ tó ń lọ ní ìgboro gbogbo ìpínlẹ̀ yìí lórí pé ọmọ ìlú wo ní í ṣe àti láti so’wọ́pọ̀ gbé Tegbe jìnnà sí àwọn aláhesọ ọ̀rọ̀, kí wọ́n lè mọ̀ pé ohun tí ó gbé lọ́wọ́ kọjá ìmọ-tara-ẹ̀ni, tí wọ́n sì sọ pé kìí se láti rọ́pò Gómìnà Abiola Ajimobi, bí kò ṣe pé láti gbé ìpínlẹ̀ yìí gòkè Àgbà.

Wọ́n ṣe àgbàsọ pé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tún nílò olùdarí ọ̀tun mìíràn, pẹ̀lú agbára láti mú òye wọ ìṣè-jọba àti láti máa wá ojútùú sí ìṣòro gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, wọ́n ní àwọn mọ̀ pé dídùn lọsàn yóò so, bí ó bá jẹ Tegbe.

Wọ́n sì tẹnu mọ pe, láti ìgbà tí Gómìnà Abiola Ajimobi ti di gómìnà ni àyípadà ọ̀tun ti bá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti pé Tegbe lo yẹ nípò láti túbọ̀ mú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ̀síwájú, wọ́n gb’óríyìn fún gómìnà Abiola Ajimobi lórí iṣẹ́ takuntakun tí ó ti ṣe, Asíwájú àtàtà fún ìgbésẹ̀ ìdàgbàsókè tí ó fi lé’lẹ̀ fún  Gómìnà tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti tẹ̀ lé, ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lákòókò ìsè-jọba rẹ, ṣe àpèjúwe Tegbe gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò Lábàwọ́n, oníwà ìrẹ̀lẹ̀, Irúfẹ́ adarí tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nílò lásìkò yìí, ẹni tí yóò gbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dé ibi tí ó lápẹ̀ẹrẹ.

Wọ́n ní ìrètí wà pé, Tegbe yóò mú àyípadà bá ìgbé-ayé gbádùn gbogbo ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nípa ìdàgbàsókè àwọn ohun a mú-ayédẹrùn, iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ohun a mú ìlú dẹrùn mìíràn àti pé ìjọba rẹ̀ yóò jẹ mọ́ ìwà rere, àìmọtara-ẹni nìkan, ìdájọ́ òdodo, ìbẹ̀rù Ọlọ́run, àti ìfẹ́ àìsẹ̀tàn láti gbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dé ilẹ̀ ìlérí àti ìdánilójú pé Tegbe kò ní yẹ àdéhùn rẹ̀ sí gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Àwọn Ẹgbẹ́ yìí ṣe àfiyèsí pé, Tegbe fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí asíwájú àti aṣojú léyìí mú kí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ yìí nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, àti pé, ó ní ìlàsilẹ àmúyangàn àti agbára láti wa ọkọ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dé ibi àṣeyọrí.

Àwọn Ẹgbẹ́ yìí tún gbà á ládùúrà fún un pé kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ìbò kòmẹsẹ̀-ẹ́-yọ wọ́n.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here