Home News Ajimobi, Gómìnà Ọ̀yọ́ Tó Kọ́kọ́ Lo Sáà Méjì Nípò, Tún Fẹ́ Lọ...

Ajimobi, Gómìnà Ọ̀yọ́ Tó Kọ́kọ́ Lo Sáà Méjì Nípò, Tún Fẹ́ Lọ Sí Sẹneti

1586
0

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ti kede pe oun nifẹ lati dije gẹgẹ bii asofin agba lasiko eto ididbo to n bọ.

Ajimọbi kede erongba rẹ yii lasiko to n sọrọ nibi eto idanilẹkọ ti ajọ alaanu Abdulsalam Abubakar seto rẹ…

Google search engine

Google search engine

Ẹkun idibo guusu Ọyọ ni Ajimọbi fẹ lọ soju nile asofin apapọ ilẹ wa lọdun 2019, labẹ ẹgbẹ oselu APC.

 “Sẹ mọ pe mo fẹ dije si ile asofin agba ilẹ wa, nitori naa ni mo se lọ feto ayẹwo ẹgbẹ wa nilu Abuja, mo si sẹsẹ de pada ni.”

Nigba to n mẹnuba ọpọ aseyọri ti ijọba rẹ ti se ni ipinlẹ Ọyọ lati ọdun mẹjọ sẹyin, Gomina Ajimọbi sọ pe, ipinlẹ toun lo tii ni alaafia julọ yika orilẹ-ede yii.

Bakan naa lo kọrin rere ki Abdulsalam Abubakar, to si se apejuwe rẹ bii ololufẹ alaafia, bẹẹ lo tun yonbo ọpọ aseyọri ilẹ ẹkọ giga fasiti Ibadan.

Laipe yi ni sẹnetọ to n soju ẹkun idibo guusu Ọyọ, Adesọji Akanbi ti kuro lẹgbẹ APC lọ si ADC, nitori erongba gomina Ajimọbi lati dije fun ipo naa labẹ ẹgbẹ oselu APC.

Previous articleShittu: I Am Poor, People Bought N22.5m APC Nomination Form For Me
Next articleOyo 2019: Ẹgbẹ́ Olóúnjẹ Ìbàdàn Se Àtìlẹyìn Fún Tegbe, Wọ́n Jẹ́rìí Sí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Rẹ̀

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here