Home Crime IWADI: Ẹni Tó Bá Lo Tramadol Lálòjù Leè Sùn, Kó Má Jí...

IWADI: Ẹni Tó Bá Lo Tramadol Lálòjù Leè Sùn, Kó Má Jí Mọ́

2028
0

Laipẹ yii ni iroyin gbalẹ kan nipa afurasi ajinigbe kan ni ipinlẹ Ondo to lo oogun Tramadol, ko to lọ sisẹ ibi rẹ, amọ ti ọwọ palaba rẹ papa segi, to si n naju lọwọ ni akata awọn ọlọpaa.

Sugbọn ohun to jọ ni loju nipa isẹlẹ naa ni pe, afurasi naa ti sun fun ọjọ mẹfa gbako lai la oju ni agọ awọn ọlọpaa, ti wọn si ni o seese ko jẹ pe oogun Tramadol to lo, lo fa oorun asun fọn-fọn n tifọn yii.

Google search engine

Idi ree ti ẹnu se n ya gbogbo eeya, ti wọn si n beere pe iru ọsẹ wo ni oogun Tramadol lee se.

Nigba to n dahun ibeere yii, Onisegun oyinbo kan, Dokita Kunle Obilade, tile iwosan ijọba ipinlẹ Ọyọ salaye pe ewu n bẹ loko longẹ ni oogun oloro Tramadol ninu agọ ara.

Bakan naa lo se ọpọ alaye nipa ohun ti Tramadol lee se ninu agọ ara;

Kin lo yẹ ko mọ nipa apọju oogun Tramadol ninu ara ?

Tramadol lee wo ara riro san ti eeyan ba mu odiwọn to yẹ ni nilo

O maa n kun ọpọ eeyan to ba loo ni oorun

Nigba mii, awọn eeyan miran to lo Tramadol, kii sun

Apọju Tramadol kii jẹ ki eeyan mọ ohun to n lọ ni ayika mọ to ba ti denu ara

Kii jẹ ki eeyan lee mi jalẹ nigba miran

Tramadol lee tete ge ẹmi kuru, ko si pa eeyan

Tramadol see fa kuro ninu ara ti ko ba tii sisẹ́ dapọ̀ mọ̀ ẹ́jẹ

Ọrọ Yoruba kan lo ni ‘asun fọn-fọn n tifọn, asun maparada ni ti igi aja’, bẹẹ́ ni ọrọ ri fun ọkunrin ajinigbe kan, ti ẹnikẹni ko ti mọ orukọ rẹ, ẹni to ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa bayii, amọ to si n sun lọ lẹyin ọjọ mẹfa to ti wa ni ahamọ, lai ta wukẹ.

Ọjọ isinmi to kọja lawọn ọlọpa mu ọkunrin naa, nigbat oun ati awọn ọmọ ikọ rẹ mẹta n gbindanwo lati ji onile itaja oogun oyinbo kan gbe lọ. ni ilu Ọwọ, tawọn mẹta yoku si ti na papa bora.

Ohun to wa jẹ iyalẹnu nibẹ ni pe, lẹyin ọjọ kẹfa, oogun Tramadol ti ajinigbe naa lo, ko to lọ sisẹ ibi rẹ, ko tii sisẹ tan lara rẹ, to si n sun lọ fọn-fọn lai ta putu ni agọ ọlọpa to wa.Ileesẹ ọlọpaa ni toju-tiyẹ, ti aparo fi n riran lawọn n sọ ọkunrin afurasi ajinigbe naa, lati mọ igba ti yoo yaju.

Kin ni ileesẹ ọlọpaa sọ ?

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, ọgbẹni Fẹmi Joseph, to fi idi ọrọ yii mulẹ ni “O dabi ẹni pe apọju oogun Tramadol 400mg ni ọkunrin naa mu, tori a ba oogun naa ni apo rẹ, eyi to fi idi rẹ mulẹ pe o mu oogun naa ko to wa sisẹ ibi ọhun.”

Joseph fikun pe ni kete ti afurasi naa ba ji, ni yoo foju wina igbẹjọ lori iwa ijinigbe to wu.

Bẹẹ ba gbagbe, a ti kede iroyin naa fun yin pe, agbára Tramadol kó òyìnbó kan yọ nilu Ọ̀wọ̀ lọwọ awọn ajinigbe nipinlẹ Ondo

Afurasi ajinigbe kan, to fẹ ẹ ji apoogun oyinbo kan gbe sun lọ fọnfọn nitori oogun oloro Tramadol to ti mu ko to lọ fun iṣẹ buruku naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Ọwọ nipinlẹ Ondo, ni iṣẹlẹ naa ti waye ati pe, titi di ọjọ Aje ni afurasi naa ṣi n sun nitori agbara oogun naa.

Lasiko to n fi oju afurasi naa han ni olu ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Ondo to wa ni ilu Akurẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ naa, Ọgbẹni Fẹmi Joseph, gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, pe afurasi naa ati awọn isọmọgbe rẹ yabo ile itaja oogun oyinbo kan nilu Ọwọ, lati ji ẹni to ni i gbe.

Joseph ni ‘ikọ ẹlẹni mẹta naa wọ ile itaja ọhun pẹlu ibọn lọwọ wọn, sugbọn ti ẹni ti wọn fẹ jigbe tete pariwo ẹ gbami, to si gba ẹnu ọna mi i sa jade.’

O ni nigba ti igbiyanju wọn lati ji i gbe ja si asan, ni awọn janduku naa sa kuro nibẹ, ṣugbọn ti ọkan lara wọn ṣubu lulẹ nitori pe ko ni agbara daadaa lataari oogun tramadol to ti lo.

‘O ti le ni wakati mẹrinlelogun ti afurasi naa ti n sun, lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ. Bakan naa ni wọn ba tabulẹti oogun tramadol kan ni apo rẹ.’

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here