Home Crime Iléẹ̀kọ́ Gbogboùnṣe Ìgbájọ Lé Gíwá Rẹ̀ Lórí Èsùn Ayédèrú Ìwé Èrí Fasiti...

Iléẹ̀kọ́ Gbogboùnṣe Ìgbájọ Lé Gíwá Rẹ̀ Lórí Èsùn Ayédèrú Ìwé Èrí Fasiti Ibadan

1622
0

Igbimọ iṣakoso ileewe gbogboniṣe aladani kan nipinlẹ Ọun, Igbajọ Polytechnic ti le oga agba ileewe naa, Ọgbẹni Akinọla Olugbenga Ọlaolu ti wọn fi ẹsun kan pe o lo ayederu iwe ẹri ikẹkọ gboye omọwe lati fasiti Ibadan.

Igbakeji alaga igbimọ majẹobajẹ ileẹkọ naa, Oloye Inaọlaji Abọaba to ba awọn oniroyin sọrọ lọgba ileewe naa ni nigba ti iroyin naa lu sita pe ayederu ni iwe ẹri imọ ijinlẹ ọmọwe ti ọgbẹni Akinọla Olugbenga Ọlaolu n gbe kiri ni wọn ti yara kọwe si fasiti Ibadan nibi ti o ni oun ti gba iwe ẹri naa lati lee fidi otitọ ọrs mulẹ.

“Abajade ifidimulẹ lati ọdọ awọn alaṣẹ fasiti Ibadan ni pe, kii ṣe ileewe naa ni iwe ẹri ti o n lo ti jade.


“Igbimọ alakoso ileewe gbogboniṣe Igbajo ṣepade lori ọrọ naa nibẹ ni wọn si ti pinnu pe ki ọgbẹni Olugbenga Ọlaolu o fi ipo giwa ileewe naa silẹ.”

Awo ọrọ nipa iwe ẹri Ọgbẹni Akinọla Olugbenga Ọlaolu lu sita ni ọsẹ diẹ sẹyin nigbati iroyin tan pe iwe ẹri ti o fi gba iṣẹ gẹgẹ bii giwa ileeks gbogbounṣe ilu Igbajọ kii ṣe otitọ ati pe arakunrin naa ko kẹkọ gboye ọmọwe, PhD ni fasiti ilu Ibadan.

Leave a Reply