Ọkọ̀ epo kan ti sàdédé gbiná, tí ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó lé ní ogún sì gbinná tẹle.
Ìròyìn náà ní ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti bá ìsẹ̀lẹ̀ náà rìn, àmọ́ kò sẹ́ni tó leè sọ iye àwọn tó kú nínú ìsẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Ìkóríta Ọ̀tẹ́dọla ní opópónà márosẹ̀ Ìbàdàn sí ìlú Èkó ni ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Àwọn èèyàn àti ọkọ̀ tó há sínú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ tó ń wáyé lásìkò tí ọkọ̀ epo náà gbinná, ló forí sọta àjálù náà.
A gbọ́ pé gbogbo àwọn èèyàn àti ọkọ̀ náà ló jóná di eérú.
A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ.
Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.