Ijọba Ipinlẹ Eko sọ pe o ti di eeyan mejila ti wọn ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba ina to ṣẹlẹ lọṣẹ to kọja.
Kọmiṣọna fun eto ilera, Dokita Jide Idris lo ṣalaye ọrọ yii l’Eko lọjọ Aje.
Eeyan mẹsan n’iroyin kọkọ gbe pe wọn ku lẹyin ti ijamba naa ṣẹlẹ, ṣugbọn dokita Idris ṣalaye pe awọn mẹwa lo ku gbara ti iṣẹlẹ ọ̀hún ṣẹlẹ, ti awọn meji si papoda nile iwosan.
Ẹwẹ, ijọba Ipinlẹ Eko ti kede pe ki ẹnikẹni to ba fura pe awọn ẹbi wọn wa lara awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ina naa kàn si ile-iṣẹ ijọba to n ri si ayẹwo DNA ati iwadii.
Ile-iṣẹ naa wa ni opopona Broad Street, to dojukọ ile itawe ni agbegbe CMS, ni Erekusu ilu Eko.