Home News FIDIO: Ajimobi Da Ilẹ̀ APC Ni — Shittu

FIDIO: Ajimobi Da Ilẹ̀ APC Ni — Shittu

1995
0
Minista fun ọna ibaraẹnisọrọ tẹ́lẹ̀, Amofin Adebayo Shittu ṣi aṣọ loju eegun ohun to ṣẹlẹ laarin oun ati gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Senetọ Abiola Ajimobi.
Adebayọ shittu sọrọ ni kikun lori ohun to ṣokunfa ija laarin wọn, eyi to pe ni Abosi lọdọ Ajimọbi.
Adebayo Shittu ni Ajimọbi da ilẹ̀ idasilẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni nipinlẹ Oyo.
O ni Ajimobi ni ko gba fun awọn ti wọn darapọ mọ APC lati ẹgbẹ CPC to jẹ pe awọn ti wọn tẹlẹ Ajimọbi wa lati ANC nikan lo n gbe sipo.
O ni nipa aisinru ìlú NYSC, APC ṣe oun to wu wọn ni APC yọ orúkọ Shittu kúrò láti kópa nínú ìdìbò abẹ́lé .
Shittu ni ko si dandan ninu agunbanirọ ki eeyan to wulo fun awujọ.
O ni Ajimọbi ro pe ti Shittu ba di gomina, oun a ran Ajimobi lọ si ẹwọn ni ‘Ó ku Shittu, ó ku Ọlọ́run lórí ohun tó fẹ́ fi san ẹgbẹ́ APC l’ẹ́san’
Shittu tun sọrọ lori ọna iṣejọba aarẹ Buhari lasiko yii ati awọn igbesẹ aarẹ lori ikọlu awọn ọmọ Naijiria ni orilẹ-ede South AfricaÀwọn ọ̀dọ́ kan ń ṣèwọ́de láti pè fún lílé àwọn àjòjì kúrò ní South Africa.
Bakan naa lo sọrọ lori idi ti APC ati ijọba Buhari ko ṣe yan oun sipo minista ni saa aarẹ Buhari keji yii.
Ni ipari Shittu mẹnuba bi gbogbo agba ẹgbẹ APC ṣe kilọ fun Ajimọbi ṣugbọn ti ko gbọ ki APC to padanu ipinlẹ Oyo ninu idibo gomina to kọja.

Watch Video as obtained from BBCYoruba

Google search engine

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here