Ọpọ awọn eekan ẹgbẹ awakọ ero lorilẹede Naijiria ni wọn peju sibi isinku oloogbe Taofeek Oyerinde ti pupọ eeyan mọ si Fẹlẹ.
Isinku rẹ waye nilu Ibadan ni ibamu pẹlu ilana ẹsin musulumi.
Lara awọn eekan to peju sibẹ naa ni MC Oluọmọ, ẹni to jẹ ilumọọka aṣiwaju ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW nipinlẹ Eko.
MC Oluọmọ ni obitibiti ero to peju kii ṣe iyalẹnu nitori irufẹ eeyan ti oloogbe Fẹlẹ jẹ nigba aye rẹ.
Lara awọn miran to peju sibẹ ni aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ, Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, awọn agba ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ ati ni apapọ orilẹede Naijiria.
Obitibiti ero kora jọpọ lati kẹdun nile alaga NURTW ẹkun gúúsù -ìwọ̀-oorunTọtun tosi ni igbe ẹkun ati idaro ti n sọ lasiko ti ẹbi, ara, ọrẹ, ojulumọ ati awọn alabaṣiṣẹ pọ kora jọpọ, lati kẹdun nile alaga ẹgbẹ awọn awakọ NURTW ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Taofeek Oyerinde Fẹlẹ, to padanu ẹmi rẹ sọwọ aisan kidinrin lọjọ isẹgun.
Fẹlẹ́, tó jẹ alága ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀ èrò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, dagbere faye lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta.
Awọn oloselu, asoju ẹgbẹ awakọ jakejado ẹkun iwọ orun-guusu, to fimọ awọn amuludun naa ko gbẹyin nile oloogbe.Lara awọn eeyan to ba ikọ BBC Yoruba sọrọ nile oloogbe ni agbegbe ẹlẹbu nilu Ibadan, ṣe apejuwe ipapoda Alhaji Fẹlẹ gẹgẹ bii adanu nla fun ẹgbẹ NURTW ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ.
Wọn fi kun ọrọ wọn wipe, oloogbe naa to dagbere faye lẹni ọdun mejidinlọgọta ni ko duro jẹ ere ise rẹ, gẹgẹ bi wọn se rawọ ẹbẹ si Ọlọrun lati tu aya, ọmọ ati awọn mọlẹbi to fi silẹ ninu. Alhaji Taofeek Oyerinde Fẹ́lẹ́, ti o jẹ alaga ẹgbẹ awọn awako NURTW ipinlẹ Ọyọ jade laye lọjọ isegun, nile iwosan to n risi itọju kindinrin nilu Abuja nipasẹ aisan kindinrin to baa finra.
Ìṣẹ́ kọ̀ndọ́ ní Fẹ́lẹ́ fí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
Alága àwọn awakọ̀ ní ìhà gúúsù-ìwọ̀-oòrùn (NURTW) Alhaji Taofeek Oyerinde tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Fẹ́lẹ́ tún jẹ́ alága ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ó kú ní ọ̀san àná ọjọ́ kẹ́jọ oṣù kẹjọ, ọdún 2018, ní ilé ìwòsàn Zenith Medical Kidney Hospital Abuja lẹ́yìn àìsàn kídìrín.
Ikede iku Fẹlẹ
Ni ọsan ọjọ Iṣẹgun ni Alhaji Fẹlẹ jade laye nileewosan Zenith Kidney Hospital nilu Abuja.
Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ lati orilẹede Saudi Arabia, Aarẹ ẹgbẹ awakọ ero l’orilẹede Naijiria, Alhaji Najeem Yasin ni ”dokita to n tọju oloogbe Taofeek Oyerinde lo pe oun lati tufọ rẹ ati pe ohun ti ṣe eto bi oku oloogbe naa yoo ṣe de ilu Ibadan lati ilu Abuja ni.
Alhaji Fẹlẹ, gẹgẹbi aarẹ ẹgbẹ NURTW lorilẹede Naijiria ṣe sọ, ti wa ni ile iwosan lati nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin, nibi ti o ti n gba iwosan fun aisan kidinrin to ba n finra.
“Ọsẹ mẹta lo ti wa ni ileewosan Zenith Kidney hospital nibi ti o ti n gba itọju.
Aisan kidinrin lo n yọọ lẹnu, aisan naa lo si ṣokunfa iku rẹ lọsan oni.”
Ki oto dagbere faye, Alhaji Oyerinde Fẹlẹ ni alaga ẹgbẹ awakọero NURTW lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria.