Iròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni àwọn alápatà takú láti tẹ̀lé àsẹ ìjọba pé kí wọn kó lọ sí ọjà ẹran tuntun, àmọ́ tí wọn yarí.
Ìdí nìyí tí ìjọba se kó àwọn ọlọ́pàá lọ sí ọjà Bódìjà láti pé wọn tẹ̀lé àsẹ ìjọba, sùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ náà bọ́wọ́ sórí.
A gbọ́ pé ẹ̀mi méjì ló bọ́ lásìkò táwọn alápatà àti ọlọ́pàá wọ̀já ìjà, tí rògbò-dìyàn sì gbòde ní ọjà náà.
Níbáyìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ti ọjà Bódìjà pa.
Nigba ti awon akọroyin de sibi isẹlẹ naa, a ri pe awọn eeyan kan ti dana sun aloku taya ọkọ loju popo, ti ọpọ eeyan si duro go go go niwaju ẹnu ọna abawọle ọja naa.
Koda, a gbọ pe diẹ ninu awọn alapata naa ti lọ si ibudo tuntun ti ijọba si fun wọn, ti awọn to fi aake kọri, lati lọ si ọja tuntun naa, si n fi apa janu.