• Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó lé ní aadota gbinná ninu isẹlẹ Iná Èkó
Èèrù ina tó jó ọ̀pọ̀ ọkọ tó sì mú ẹmi lo nilu Eko tí n tútù ṣugbọn àrà àwọn ọmọ Nàìjíríà sí n gbóná lórí ìṣẹlẹ náà.
Lójú òpó Twitter, iriwisi loriṣiiriṣii ní wọn tí n sọ ti ọpọ sí dá lórí pe ki ọkọ epo ma rìn lójú ọsán mọ.
Ìṣẹlẹ náà to waye lagbègbè Ìkóríta Ọ̀tẹ́dọla, Berger, ní opópónà márosẹ̀ Ìbàdàn sí ìlú Èkó lọjobo ní ọpọ èèyàn tí ṣé àpèjúwe rè gẹgẹ bí ìṣẹlẹ tó gbenilọkan soke
Àwọn kàn ní ìjọba kò gbọdọ̀ fí ọwọ yẹpẹrẹ mú ọrọ̀ yí nítorí ìpalára tí àwọn ọkọ èpo àti àjàgbé n ṣé fún ará ìlú kọjá afẹnuso.
Ninu iriwisi tire, Dokita Dipo Awojide ni adura pe ki irufe isẹle bayi ma waye mọ ko le tan ọrọ to wa nile yi bi kò ṣe pe ki ijọba wa wọrokọ fi ṣada lori ipenija ijmaba ina ọkọ agbepo.
Babalola bẹnu ẹtẹ lu bi awọn ohun amaye dẹrun gege bi ọkọ ojurin ati ile ise ipọnpo ko se sisẹ to ni Naijiria.
O ni bi wọn ba n sisẹ ni,ijamba bi ti teko to sẹlẹ ko ba ma waye.
JJ Omojuwa ni asiko ti to bayi ki awọn olori orileede Naijiria se ojuse wọn bo ti se to ati bo ti se ye.