Home Entertainment #FreshFM: Ayefele Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Ìjọba Ọ̀yọ́, Arulogun Fún Ibi Tiwon ‘Sìn Mí...

#FreshFM: Ayefele Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Ìjọba Ọ̀yọ́, Arulogun Fún Ibi Tiwon ‘Sìn Mí Dé’

2450
0
#

#

Oludasilẹ ileesẹ Fresh Fm, Yinka Ayefẹlẹ ti fesi si bi ijọba ipinlẹ Ọyọ se wo ileesẹ redio naa ni kutu hai aarọ ọjọ Aiku.

Yinka Ayefẹlẹ, lasiko to n sọrọ lori redio ọhun, Fresh FM, to bẹrẹ isẹ pada lẹyin wakatai meji ti ijọba wo ile naa, rọ awọn araalu to n se atilẹyin fun-un, lati mase da rogbodiyan kankan silẹ lori isẹlẹ naa.

#

Bakan naa lo tun rọ wọn lati mase jo ọkọ Ajumase ti ijọba gbe sẹba ileesẹ́ naa, lọna ati gbẹsan lara ijọba.

O tun dupẹ lọwọ gbogbo agbaye fun atilẹyin wọn pẹlu afikun pe ibi to ba le, la n ba ọmọkunrin.

“Ẹ ni suuru, ẹma fa rogbodiyan, to ba jẹ pe lootọ lẹ́ ni ifẹ́ mi, mo bẹ yin ni, ẹ mase jo ọkọ ijọba to wa nilẹ. Bi ijọba tilẹ wo ileesẹ, amọ redio Fresh FM ko lee wo lailai, tori araalu lo nii.”

Ayefẹlẹ ni “niwọn igba ta a ba ti se ohun to lodi sofin, taa si bu ijọba, taa si se ohun to lodi si ilana eto igbohunsafẹfẹ́, ẹyin ẹ fi idajọ silẹ sọdọ Ọlọrun, ẹ jẹ ka fa wọn si kootu Ọlọrun.

“Bakan naa ni Ayefẹlẹ tun dupẹ́ pupọ lọwọ ijọba ipinlẹ Ọyọ fun ibi ti wọn sin oun de, o si tun dupẹ lọwọ kọmisana feto iroyin, Toye Arulogun, pe oun lo pilẹ ọrọ bi wọn yoo se wo ile oun, oun si ki pe o ku aseyọri lori isẹ naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here