Gbọnmisi omi o to o n waye lori taa ni alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ogbomọsọ ko tii lọ ree sinmi o.
Idi ni pe Ọlamijuwọnlọ, tii se ọmọ bibi Ọtunba Adebayọ Akala, ti kin baba rẹ lẹyin pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ko ni atilẹyin ofin lati yọ oun nipo.
Ọlamiju salaye pe ara lo n ta ẹgbẹ APC, nitori pe oun pada sẹgbẹ baba oun, tii se PDP, ti kanselọ mẹrin ninu mẹjọ si wa lẹyin oun.
O fikun pe awọn eeyan ilu Ogbomosọ nikan lo lee yọ oun nipo, kii se Kọmisana, bẹẹ si ni ko sẹlẹ ri, ki Kọmisana maa bura fun alaga ijọba ibilẹ.
O wa fọwọ gbaya pe pe ile ẹjọ ni yoo ba oun ati ijọba ipinlẹ Ọyọ da si ọrọ naa.